Words and Music composed, written and arranged by Olusegun Akinlolu. No part of these lyrics should be shared in any form or any public space without giving credit to the writer. All rights reserved. English translations in italics.

© & ℗ 2018 EniObanke

 

BẸRIWỌN

Gbogbo àwọn tó nfẹ́ ètò ìlú

Gbogbo àwọn tó ngbèrò kó lè da

Gbogbo àwọn abániṣé k’ọ́la kó lè dùn

Gbogbo àwọn ọlọ́wọ́ àtúnṣe o

Bẹ́ẹríwọn lọ́nà ọjà ẹ bá nké sí wọn yé

Bẹ́ẹríwọn lókè odò ẹ bá nbá wọn sọ̀rọ̀

Pé ‘ṣẹ́ ti yá o, àsìkò ti tó

Ọjọ́ ta wí yẹn o, ó ti sún mọ́

Ẹ jẹ́ a gbáradì

Pé ‘ṣẹ́ ti yá o, àsìkò ti tó

Ọjọ́ ta wí yẹn o, ó ti dé tán

Ẹgbẹ́ atúnlù́tò

 

Gbogbo àwọn ìyá ọlọ́wọ́ ìtọ́jú

Gbogbo àgbà ọlọ́gbọ́n atọ́nisọ́nà

Gbogbo àwọn tí ò fẹ́ kí’re kó sọnù

Gbogbo àwọn ọ̀dọ́ akínkanjú ẹni ire

Bẹ́ẹríwọn lọ́nà ọjà ẹ bá nké sí wọn yé

Bẹ́ẹríwọn lókè odò ẹ bá nbá wọn sọ̀rọ̀

Pé ‘ṣẹ́ ti yá o, àsìkò ti tó

Ọjọ́ ta wí yẹn o, ó ti sún mọ́

Ẹ jẹ́ a gbáradì

Pé ‘ṣẹ́ ti yá o, àsìkò ti tó

Ọjọ́ ta wí yẹn o, ó ti dé tán

Ẹgbẹ́ atúnlù́tò

 

All those who want the society returned to sanity

All those thinking of how to make things better

All those making sacrifices for a better future

All those committed to working for positive change

If you see them on the way to the market, please call on them

If you see them on the bank of the river, please have a word

The work is now, the time has arrived

The day we have been waiting for is imminent,

Let us get ready

The work is now, the moment is here

The day we have been waiting  for is imminent,

Reformer’s club

 

All the mothers with nurturing hands

All the wise elders and guides 

All those who don’t want the treasure to be lost

All the valiant youth with good hearts

If you see them on the way to the market, please call on them

If you see them on the bank of the river, please have a word

The work is now, the time has arrived

The day we have been waiting for is imminent,

Let us get ready

The work is now, the moment is here

The day we have been waiting  for is imminent,

Reformer’s club

 

ALL OF ME

I went looking for nothing, then I found you

You said, “Hold on to something” and you were right

All my coming and going ends right here with you

Now I’m dreaming of everything and it’s alright

You took me dancing, then we went walking

Climbed some mountains, fell in a sea of joy

My dreamergirl, you make me so happy

And if I could I would make a home here

Spirit child, you’ve got me feeling groovy

Where you go there I’m coming too

I’m coming whole, I’m coming all of me

 

Tacky worries and heartaches, those were my clothes

Blind, stumbling around, lonely and broken

You said, “Raise your head up, can’t you see the light?”

Now I’m dreaming of everything and it’s alright

It feels like flying or levitating

My river’s flowing straight to a sea of joy

 

Can you feel it, what I’m feeling?

Do you know it, where I am?

 

AWOKỌṢE

Kò yẹ k’áwọn tó nṣ’iṣẹ́ ma jìyà láyé

Àwọn ló yẹ kó ma jẹ̀ gbádùn, ló yẹ ká ma lò fi ṣ’àwòkọ́ṣe

Ṣùgbọ́n n’ílé aláìṣòótọ́ ẹni nṣ’iṣẹ́ mà ló njẹ baba nlá ìyà

Ọ̀la nbọ̀ kíákía, ọ̀rẹ́ ẹ jẹ́ ká gbìmọ̀

Jọ̀wọ́ ẹ jẹ́ a kó’ŕa jọ ṣ’àtúnṣe

 

Kò yẹ k’ẹ́ni tí nbẹ n’ípò nlá ṣe’un ìbàjẹ́

Àwọn ló yẹ kó ma wù’wà gidi, ló yẹ ká ma lò fi ṣ’àwòkọ́ṣe

Ṣùgbọ́n n’ílù́ olópùrọ́ ẹni ọwọ́ ẹ̀ ò mọ́ mà ló ndọlọ́rọ̀ pàtàkì

Ọ̀la nbọ̀ kíákía, ọ̀rẹ́ ẹ jẹ́ ká gbìmọ̀

Jọ̀wọ́ ẹ jẹ́ a kó’ŕa jọ ṣ’àtúnṣe

 

Kò yẹ k’áwọn tó nṣ’iṣẹ́ rere jìyà láyé

Àwọn ló yẹ kó ma jẹ̀ gbádùn, ló yẹ ká ma lò fi ṣ’àwòkọ́ṣe

Ṣùgbọ́n n’ílù́ aláìmọ̀kan, orí mà ti jìyà ó ti di sálúbàtà

Ọ̀la nbọ̀ kíákía, ọ̀rẹ́ ẹ jẹ́ ká gbìmọ̀

Jọ̀wọ́ ẹ jẹ́ a kó’ŕa jọ ṣ’àtúnṣe

 

Ibi ire ni ká bá ẹ o ọmọ

Má mà bá wọn gbìmọ̀ ọ̀tẹ̀, má mà bá wọn wù’wà ìbàjẹ́

Ìwà ire ni ká bá lọ́wọ́ e ọmọ

Má mà bá wọn ṣe mọ̀dàrú, Má mà bá wọn wù’wà ìkà

 

It’s not right that those who do toil in honesty should suffer

They are the ones who should be prosperous and used examples

But in the home of corruption, those are the ones who hurt the most

The future arrives quickly friends, let us make a plan

Let’s come together and reform the system

 

It is not right for those in authority to misbehave

They should be the ones doing right and held up as a standard

But in the nation of liars, those with unclean hands become powerful

The future arrives quickly friends, let us make a plan

Let’s come together and reform the system

 

It is unfair that those do good things have such a hard life

They are the ones who should flourish and be promoted as a model

But in the land of retards, the head suffers the fate of the shoe

The future arrives quickly friends, let us make a plan

Let’s come together and reform the system

 

You should only be met in good places, child

Don’t join in formenting chaos, don’t partake of evil practices

Only good acts should be met in your hands, child

Don’t partake of destructive acts, don’t engage in wickedness

 

ABANIJẸ

Ọ̀tá inú, ọ̀tá òde, kò gbèrò míràn ju pé kó bàjẹ́

Gbogbo ayé ngbìmọ̀ wípé kó lè da 

Abanijẹ́ nṣ’ẹnu gọ̀ngọ̀ láti sọ̀rọ̀

 

Abanijẹ́ nṣe’ni kò mọ̀ pé kò da

Ọ̀tá inú, ọ̀tá òde, kò gbèrò míràn ju pé kó dàrú

Gbogbo ayé nṣè’tò wípé kó lè jọ o

Abanijẹ́ nṣ’ẹnu gọ̀ngọ̀ láti sọ̀rọ̀

 

The slanderer destroys without realizing it

Enemy from within, enemy from without

He has no other thought than for chaos to reign

Everyone is meeting, planning for things to be better

The slanderer dares to open his mouth to talk

 

EVERY LITTLE THING

May your sun shine through the day

May your star brighten up the night

May you find calm when troubled

May you not be broken and lost

May you find joy in every little thing

And peace for your soul

 

May the wind sing your name

May the mountains bow down to you

May the dark clouds dissolve into rain

May they fall down in showers of blessings

May you find joy in every little thing

And peace for your soul

 

Happiness is a choice my friend

Reach for it, make the move

Love is here when you need it

Can you feel it, feel it, deep in the groove?

 

May your heart be filled with hope

For the moment of worry is gone

May your dreams come alive

Bring your colours, paint the walls in glitter

May you find friends when you need a hand

May you remain whole

 

Happiness is a choice my friend

Reach for it, make the move

Love is here when you need it

Can you feel it, feel it, deep in the groove?

 

ỌJỌ TUNTUN

A ìí f’ọmọ ọrẹ̀ bọ’rẹ̀ ni wọ́n nwí

Àwa ti ṣí’ṣọ lójú òrìṣà - Èèwọ̀!

Èèmọ̀ ṣakọ wọ̀ ‘lú o, ìpọ́njú nló fà dání o

Kò s’óun ta lè gbé ṣe, kò mà s’óun ta lè dà

Bí ò bá s’áyọ̀ ní’lé o (k’ẹ máa gbọ́ ará mi)

Òtúbántẹ́ ni, òfo lásán

Bí ò sí ‘dùnnú lọ́dẹ̀dẹ̀ o, 

Òtúbántẹ́ ni, òfo ló jẹ́

 

À ńbẹ̀ yín ò ẹni ire, 

Jẹ́ ká so’wọ́ pọ̀, ká fi’nú ko’nú

À ńretí àtúntò, ìdẹ̀ra, 

Ọwọ́ wa la ó fi ṣé

 

Ẹ̀té l’ọba àìṣọ́ra, ìdààmú ní tẹ̀lé àìṣètò

Èèmọ̀ g’ẹṣin wọ̀ ’lú o, ìfàsẹ́yìn àtìrandíran

Kò s’óun ta lè gbé ṣe, kò mà s’óun ta lè dà

Bí ò bá s’áyọ̀ ní’lé o (k’ẹ máa gbọ́ ará mi)

Òtúbántẹ́ ni, òfo lásán

Bí ò sí ‘dùnnú lọ́dẹ̀dẹ̀ o, 

Òtúbántẹ́ ni, òfo ló jẹ́

 

À ńbẹ̀ yín ò ọlọ́gbọ́n ayé

Kẹ tọ́ wa s’ọ́nà àbáyọ s’íre

À ńretí àtúntò, ìdẹ̀ra, 

K’ọ́jọ́ tuntun tàn yan yan

 

It is forbidden to sacrifice a deity’s child to him

But we have stripped the gods naked

And now calamity saunters into town

It comes along with pain and suffering

Whatever we achieve or become,

If there’s no joy at home, it is all a waste

If there is no happiness in the community,

It is all in vain

 

We beg of you people of goodwill

Let us rub minds and join hands

We desire societal reform and well-being

It is by ourselves that we will make it happen

Disgrace arises from carelessness, unrest from lack of planning

Calamity rides into town, cross-generational retardation

Whatever we achieve or become,

If there’s no joy at home, it is all a waste

If there is no happiness in the community,

It is all in vain

 

We beg of you wise ones

Please show us the way to salvation and progress

We desire societal reform and well-being

The dawn of a bright, new day

 

IJO ONI

Gbogbo ọmọdé ẹ̀yin ni’jó kàn

Ẹ bọ́ s’ágbo o, ijó òní yíò ládùn, yíò lárinrin

Ẹỳin ọ̀dọ́ ẹ̀yin ni’jó kàn

K’ẹ bọ́ s’ágbo o, ká ṣ’eré, yíò ládùn, yíò lárinrin

 

Ijó ìdẹ̀ra, ijó ìdùnnú, ijó ọpẹ́, ijó ayọ̀

Ijó àtúnjó, ijó tuntun, ijó àláfíà

Ijó àjọjó, ijó ẹgbẹ́, fọwọ́kanwọ́ fẹsẹ̀lusẹ̀

Ijó àfapáfòbíẹyẹ, jùdí wùkẹ̀-wukẹ

Gbogbo ọmọge ẹ̀yin ni’jó kàn

Ẹ bọ́ s’ágbo o, ijó òní yíò ládùn, yíò lárinrin

Ẹỳin ìyá ẹ̀yin ni’jó kàn

K’ẹ bọ́ s’ágbo o, ká ṣ’eré, yíò ládùn, yíò lárinrin

 

Gbogbo ọkùnrin ẹ̀yin ni’jó kàn

Ẹ bọ́ s’ágbo o, ijó òní yíò ládùn, yíò lárinrin

Gbogbo obìrin ẹ̀yin ni’jó kàn

K’ẹ bọ́ s’ágbo o, ká ṣ’eré, yíò ládùn, yíò lárinrin

 

Ijó pẹ̀lẹ́, ijó ìbùkún, ijó ọ̀rẹ́, ijó ògo

Kò s’ájèjì lójú agbo, ijó ìfẹ́ ni o

Ijó ẹ̀rín, ijó ìrètí, ijó ọlọ́gbọ́n àt’ẹní nfẹ́’re

Apá lọ̀tun, ẹsẹ̀ losì, rè’dí rùbùkẹ̀-rubukẹ

Gbogbo ìlú ẹ̀yin ni’jó kàn

Ẹ bọ́ s’ágbo o, ijó òní yíò ládùn, yíò lárinrin

Gbogbo oníjó ẹ̀yin ni’jó kàn

K’ẹ bọ́ s’ágbo o, ká ṣ’eré, yíò ládùn, yíò lárinrin

 

Children it is your turn to dance

Come on the floor, this dance will be great fun

Young folks, it is your turn to dance

Come on the floor, this dance will be great fun

 

It’s a dance of peace and happiness, thanksgiving and joy

It’s an old dance, a new one, a dance of well-being

It’s one we do together, a group dance, arms and legs touching

Arms flapping like birds, waists wiggling luxuriously

Young ladies, it is your turn to dance

Come on the floor, this dance will be great fun

Mothers, it is your turn to dance

Come on the floor, this dance will be great fun

 

All the men, it is your turn to dance

Come on the floor, this dance will be great fun

All the women, it is your turn to dance

Come on the floor, this dance will be great fun

 

A gentle dance, of blessings, for friends, of glory

There are no strangers here, it’s a dance of love

Of laughter and hope, for the wise and seekers of good fortune

Arms right, legs left, waists wiggling luxuriously

Townsfolk, it is your turn to dance

Come on the floor, this dance will be great fun

All you dance gurus, it is your turn to dance

Come on the floor, this dance will be great fun

 

ỌMỌYẸNI

Ọmọ́yẹni mà ti d’àràbà s’ọ́nà

Ọmọ́yẹni d’ẹyẹ òkè tó nfò lẹlẹ

 

Ìran akin ní dúró f’ojú gbo’gun, gbé’ra ọmọ akin

Kìnìún ṣ’óun l’ọba ẹran kìí bẹ̀rù f’ẹ́ran lóko

Ògòngò ṣá nl’ọba ẹyẹ, kìí gbọ̀n jìnì f’ẹ́yẹkẹ́yẹ

Olúborí l’ókè, olúborí n’ílẹ̀, 

Olúborí l’ọ́nà, olúborí lókolódò

 

Omoyeni has transformed into a mighty tree

Omoyeni, flies high like a bird in the sky

 

The clan of courage never fears war, get up scion of the brave

The lion, the king of all animals fears no beast in the forest

The ostrich, king of all birds never trembles before one

You are a conqueror in the sky, a conqueror on land

Conqueror on the road, in the wild, and on the seas

 

LOST

Don’t think about him or what you had before

Times come and times go, 

And there’s no reason to live in the past

Don’t dwell in that could, come it’s a new day

It’s time to reach for new arms

To hold you when you’re falling down

You’d better give it up - what’s lost is lost

Time you should forget it, forget the pain

You’ve got to light a new path for yourself

What’s lost is lost

 

You’re hurting so bad, looks like no way back

Your thoughts are broken in many pieces

A puzzle you can’t even figure out

Crack open the window, let in some sunshine

Inhale some fresh breeze

And if you want you can go all the way

 

Is this the answer that you seek?

Can you hear me? I don’t have the words for it

Is the way that we must take?

New beginnings, it’s no riddle anymore

 

ALAṢELA

Bí mo bá ti r’ẹ́ni mi, inú mi á dùn, ara mi á yá gágá, 

Ma r’ẹ́̀rín ayọ̀, ma r’ẹ́̀rín ìdùnnú, ma k’ọrin tuntun

Bí mo bá ti r’ẹ́ni mi, inú mi á dùn dé lẹ̀, ara mi á yá gágá, 

Ma j’íjó ayọ̀, ma r’ẹ́̀rín ìdùnnú

 

Jomijòkè ọlọ́wọ́-aró, ẹni mi àtàtà, ọjọ́ ti mọ́, 

Ojú ayé ti là - gbé’ra ko pàdé mi lóde

Ọ̀faragbìjà, alápá-ajé, aya mi àtàtà, ojú ti mọ́, 

Ọ̀nà ọ̀tun ti là - bóóde jàre

 

Wá ká lọ s’ọ́jà ìdẹ̀ra, ká mú ‘re bọ̀ wálé

Ọjọ́ òní ọjọ́ aláṣelà mà ló jẹ́

Wá ká lọ s’ókè ìdùnnú, ká m’áyọ̀ bọ̀ wá lé

Ọjọ́ òní ọjọ́ olóyin

Jomijòkè ọlọ́wọ́-aró, ẹni mi àtàtà, ọjọ́ ti mọ́, 

Ojú ayé ti là - m’áṣọ wọ̀ pàdé mi lóde

Ọ̀faragbìjà, alápá-ajé, aya mi àtàtà, ojú ti mọ́, 

Ọ̀nà ọ̀tun ti là - bóóde jàre

 

Wá ká lọ s’ódò ìṣẹ́gun, ká f’àwọ̀n kó’re

Ọjọ́ òní ọjọ́ aláṣelà mà ló jẹ́

Wá ká lọ s’ọ́dọ̀ àgbà, k’ọ́n súre fún wa

Ọwọ́ àwa t’olúborí ni

Jomijòkè ọlọ́wọ́-aró, ẹni mi àtàtà, ọjọ́ ti mọ́, 

Ojú ayé ti là - múra ko pàdé mi lóde

Ọ̀faragbìjà, alápá-ajé, aya mi àtàtà, ojú ti mọ́, 

Ọ̀nà ọ̀tun ti là - bóóde jàre

 

Wá ká lọ s’ókè ìlera, k’ágbára d’ọ̀tun

Ọjọ́ òní ọjọ́ àláfíà mà ló jẹ́

Wá ká lọ s’ọ́gbà ìtura b’óòrùn bá wọ̀ tán

Ká jó ká yọ̀, ijó alábùkún

 

When I see my beloved, my heart is gladdened

I feel uplifted, smile with joy and sing a new song

When I see my beloved, my heart is deeply gladdened

I feel elated, dance with joy and laugh happily

 

My darling, mystery of land and sea with dye-stained hands

It’s a new day, the world is awake, arise and meet me outside

My dear wife - good heart and hands of fortune

Day has dawned, a new path is open, please come on out

 

Come, let’s go to the Market of Peace and return with bounties

This is a day of outstanding success

Come, let’s go to Happiness Hill, and return with joy

This day, sweet like honey

My darling, mystery of land and sea with dye-stained hands

It’s a new day, the world is awake, dress up and come out

My dear wife - good heart and hands of fortune

Day has dawned, a new path is open please come on out

 

Come, let’s go to the River of Victory and harvest goodness

This is a day of outstanding success

Come, let’s go to the elders that they may bless us

Ours hands are those of conquerors

 

Come, let’s go to the Mount of Wellness, re-new our energy

This is a day of good health

Come, let’s go to the Garden of Leisure when the sun has set

We shall dance and rejoice, a dance of the blessed

 

TOMORROW STILL

Through the eyes of day to the gut of night

Fell with the fall and slid in the storm

But we’re here, still here

We’re here, very much here

Been a pawn in the game for too long my friend

The cord of trust broken too many times

But we’re here, still here

We’re here, very much here

We could break it up to build it again

We could pull it apart and go our separate ways

Or we can dream and hope

 

Would it not be better if we took a new way

Would it not be better?

Would it not be better a moment of joy

Would it not be better?

I’m thinking big, running swift in a dream

My pocky face reflected

Pretty, so pretty in your eyes

See what we’ve done…

Would it not be great tomorrow still?

Follow

YouTube -- https://www.youtube.com/user/Awilele Twitter -- https://twitter.com/Beautiful_Nubia Instagram -- https://instagram.com/beautiful.nubia/ Facebook -- https://www.facebook.com/beautifulnubia CD Baby -- http://www.cdbaby.com/Artist/BeautifulNubiaandtheRootsRenai