OLUMUYIWA

Words and Music composed, written and arranged by Olusegun Akinlolu. 

No part of these lyrics should be shared in any form or any public space without giving credit to the writer. All rights reserved. 

© & ℗ 2023 EniObanke

English translations of Yoruba lyrics are in italics beneath each song.

 

1. A LE TENTE

T’a l’ó wà ní’bẹ̀, t’a l’ó wà t’á ó pè ní’ṣẹ́

Àwọn ọ̀rẹ̀ wa wọ́n wà ní’bẹ̀, wọ́n pọ̀ t’a pè ní’ṣẹ́

Wọ́n mí w’ọ̀nà f’ẹ́ni nṣì’nà

Wọ́n mí là’nà f’ẹ́ni nrìn bọ̀

Wọ́n mí gb’èrò wípé k’ó lè da

Wọ́n mí ṣ’ìpẹ̀ f’ẹ́ni nṣ’ọ̀fọ̀

Wọ́n mí pèsè f’aláìrí

Wọ́n mí ṣè’tò wípé k’ó lè da
 

Ẹgbẹ́ aláyọ̀, ẹgbẹ́ oníre npè yín sẹ́

Àwọn ọ̀rẹ́ wa wọ́n wà ní’bẹ̀, wọ́n pọ̀ t’a pè ní’ṣẹ́

Wọ́n mí gbè’jà f’ẹ́ni njà’jà rere

Wọ́n mí p’ẹ̀tù sí’nú fùfù

Wọ́n mí gb’èrò wípé k’ó lè da

Wọ́n mí wò’kè f’ẹ́ni nwo’lẹ̀

Wọ́n mí wo’lẹ̀ f’ẹ́ni nwò’kè

Wọ́n mí ṣè’tò wípé k’ó lè da

 

Gbogbo ẹ̀dá mà la pè, gbogbo yín mà la pè ní’ṣẹ́

Àwọn ọ̀rẹ́ wa wọ́n wà ní’bẹ̀, wọ́n pọ̀ t’a pè ní’ṣẹ́

Wọ́n mí w’ọ̀nà f’ẹ́ni nṣì’nà

Wọ́n mí là’nà f’ẹ́ni nrìn bọ̀

Wọ́n mí gb’èrò wípé k’ó lè da

Wọ́n mí ṣ’ìpẹ̀ f’ẹ́ni nṣ’ọ̀fọ̀

Wọ́n mí pèsè f’aláìrí

Wọ́n mí ṣè’tò wípé k’ó lè da

Wọ́n mí gbè’jà f’ẹ́ni njà’jà rere

Wọ́n mí p’ẹ̀tù sí’nú fùfù

Wọ́n mí gb’èrò wípé k’ó lè da

Wọ́n mí wò’kè f’ẹ́ni nwo’lẹ̀

Wọ́n mí wo’lẹ̀ f’ẹ́ni nwò’kè

Wọ́n mí ṣè’tò wípé k’ó lè da

 

A fò a lé ténté, a fò - àwa d’ọ̀rẹ́ ìdùnnú

A fò a lé ténté, a fò - àwa jogún ìdẹ̀ra

A fò a lé ténté, a fò - àwa bo’rí àìmọkan

A fò a lé ténté, a fò - àwa bo’rí ìkórira

A fò a lé ténté, a fò - àwa bo’rí ìwà ibi

 

Who is there? 

Who is there to send on this mission? 

Our friends are there

Many of our friends are engaged on this mission

Providing clarity for those who are lost

Clearing the path for future wayfarers

Always thinking of how to make things better;

Consoling the broken-hearted

Providing for those in need

Working to make things better for all.

 

The union of joy and goodness invites you

Our friends are there

Many of our friends are engaged on this mission

Supporting those in the struggle for justice

Calming those who are embittered

Always thinking of how to make things better;

Looking up for those looking down

Looking down for those looking up

Working to make things better for all.

 

Everyone is called

All of you are called to this mission

Our friends are there

Many of our friends are engaged on this mission

Providing clarity for those who are lost

Clearing the path for future wayfarers

Always thinking of how to make things better;

Consoling the broken-hearted

Providing for those in need

Working to make things better for all.

Supporting those in the struggle for justice

Calming those who are embittered

Always thinking of how to make things better;

Looking up for those looking down

Looking down for those looking up

Working to make things better for all.

 

We fly high, up at the top - happiness is our reward

We fly high, up at the top - peace is our inheritance

We fly high, up at the top - beyond ignorance

We fly high, up at the top - beyond hatred and bigotry

We fly high, up at the top - beyond all bad values.
 

2. AIMOKAN

Ṣ’ówó ló wùn ọ́, t’ó nwá, t’ó nsá’ré kìràkìtà?

Àbí ‘lé lo fẹ́ kọ́, tó gùn ọ́ l’ọ́kàn, t’ó nbẹ́ jàùjàù o?

Kò sí’re t’á nfẹ́ tí ẹ̀dá kò ní rí b’ásìkò bá tó

K’á sáà ma wù’wà ‘re l’ó tọ́ o

K’a sáà ma wù’wà gidi ọ̀rẹ́ mi l’áyé
 

Mo rí ọ t’o gb’ẹ́rù l’órí l’ọ̀sán tí òòrùn tàn yanyan

Mo tún rí ọ l’ọ́gànjọ́ t’o gbé’un s’éjìká nmí hílàhílo o

Bó ti wù k’ó ti rí, ire ẹ̀dá kò ní kọjá rẹ̀ b’ópẹ́b’óyá o

K’á sáà ní sùúrù l’ó tọ́ o

K’á sáà n’ítẹ̀lọ́rùn ọ̀rẹ́ mi l’áyé
 

Ilara ò l’érè ẹ gbọ́ mi, ó nsọ ni d’èrò ẹ̀yìn ni

Òòrùn ò ní ràn títí títí k’ó gba ‘ṣẹ́ òṣùpá ṣe l’ókè

Ojú ọ̀run t’ẹ́yẹ fò lẹ́gbẹgbẹ̀rún l’áì f’ara kan’ra o

K’á sáà l’áforítì l’ó tọ́ o

K’á sáà n’íwà tútù ọ̀rẹ́ mi l’áyé

 

Ṣ’ọ́gbọ́n l’ó wùn ọ́, t’ó nwá, t’ó nbẹ́ gìjàgìjà kiri?

Àbí’yì l’ò nfẹ́, kí gbogbo ayé máa wá rìrì fún ẹ o?

Ire ò ní kọjá on’íre, ojú mà ní pẹ́ sí o

K’á sáà ma wù’wà ‘re l’ó to o

K’á sáà ma wù’wà gidi ọ̀rẹ́ mi l’áyé
 

Àìmọ̀kan l’ó ndàmú ẹ̀dá o 

L’ó ndàmú ènìyàn t’ó nṣè’páyà fún ọ̀la

Ìgbà àwa y’ó l’ádùn gan, y’ó láyọ̀ púpọ̀

K’á sáà ma wù’wà ‘re l’ó tọ́ o

K’á sáà ma wù’wà gidi ọ̀rẹ́ mi l’áyé
 

What is it you’re seeking that’s made you so restless?

Is it the desire for wealth or a house of your own?

All the reward we seek shall be ours in due season

What matters is to be of good character.
 

I see you heavy-laden at noon in the hot burning sun

I see you again at night, load on your shoulders, breathing hard

Not withstanding, one’s good fortune will not pass one by

What matters is to have patience and contentment.

 

Backwardness is the reward of those possessed of bitter envy

However strong its rays, the sun never assumes the moon’s role

The sky is wide enough for thousands of birds to fly without touching wings

What matters is to have perseverance and calmness.

 

What is it you’re seeking that’s made you so restless?

Is it wisdom or fame, so that you earn the respect of everyone?

All the reward we seek shall be ours in due season

What matters is to be of good character.

 

Lack of wisdom is why folks panic about the future

Our days will be full of joy and sweetness

What matters is to be of good character.

 

3. CHARIOT OF MELODY

Early morning

Gentle sunlight in my eyes

Got this feeling I can’t lose, oh yeah

On the road to happiness, sitting pretty, feeling good

I’m the one who’s got the goods, got the groove

Got the moves, oh yeah

And if you’re ready…

Chariot of melody take me up high

Take me up high above these clouds

I am the product of a thousand daydreams

Take me up high beyond this dark ol’ place

 

Everybody’s here

Full of courage, seeking hope

Got the feeling it’s our time, oh yeah

On the road to something great, new beginnings full of joy

We’re the ones who’ve got the answers, got the truth

And the rhythm, oh yeah

When you’re ready…

Chariot of melody take us high

Take us high above these clouds

We are the evidence of a million wishes

Take us high beyond this dark ol’ place

 

Don’t hold your breath now

This is not a passing phase

Folks are really on the move, oh yeah

On the road to sweet relief, true reform beyond belief

They’re the ones who’ve got the goods, got the groove

Got the moves, oh yeah

When you’re ready…

Chariot of melody take us high

Take us high above these clouds

We’re the reality of ageless visions

Take us high beyond this dark ol’ place

 

4. ISE L’ADURA

Iṣẹ́ mà l’àdúrà ẹni

Àgbà t’ó m’òye ẹ jọ̀wọ́ ẹ tọ́’mọ s’ọ́nà òtítọ́

K’ọ́n lè ṣe’re l’áyé

Iṣẹ́ yẹn làwúre gangan

Àgbà t’ó m’òye ẹ jọ̀wọ́ ẹ kọ́’mọ ní’wà gidi

K’ọ́n lè ṣe’re l’áyé

 

Ẹni nfẹ́’re l’óko

Ìyẹn á dẹ’lẹ̀ f’ọ́kà

Á t’èbù bọ’lẹ̀ l’ásìkò, á ro’ko, á kọ’bè

Ẹni nwá èrè ọjà

Ìyẹn á k’óun sí’lẹ̀

Á s’ẹ̀rín s’ọ̀yàyà, á p’olówó, á f’oníbàárà mọ́’ra
 

Ẹni nwá ọrọ̀ inú ibú

Ìyẹn á ti’kọ̀ s’ómi

Á s’àwọ̀n s’ódò gbalaja, níbi t’áwọn ẹja pọ̀ rẹpẹtẹ

Ọlọ́dẹ àná ò f’ẹnu p’ẹran

Nṣe ló gbé’ra ní’lẹ̀

Tó wọ’nú aginjù lọ láìbẹ̀rù f’éwu tí nbẹ l’ọ́nà

 

Fọwọ́pawọ́ ngò rí nkan (ṣ’iṣẹ́, fi sùúrù si)

Fẹsẹ̀pasẹ̀ ngò rí nkan (ṣ’iṣẹ́, fi òtítọ́ si)

Tojúbọlé ẹ ò r’erè níbẹ̀

Sẹbọṣòògùn òtúbántẹ́

Jágbójájù láìláròjinlẹ̀

Ògbójúwòkè w’Elédùmarè

Sebí’ṣẹ́ yẹn l’àdúrà ẹni

Àní ‘ṣẹ́ yẹn l’àwúre gangan
 

One’s labour is the real prayer

You wise elders, please show the children the true path

That they may succeed in life.

Work is the true good luck charm

You wise elders, please teach the children good values

That they may do well in life.
 

He who wishes to profit from farming

Must till the earth, make heaps

And plant seeds at the right time.

He who desires profitable trade in the market

Must display and advertise his wares,

And cheerfully invite customers.

 

He who seeks the riches of the sea

Must set out in a boat, cast his net far and wide 

Where the fishes are known to be plenty.

The famous hunter of yore didn’t get game by talking

He got up and set out for the forest 

Without any fear of what could lay ahead.

 

Don’t stay there rubbing your hands together

Work, and embrace patience

Don’t just be there rubbing your feet together

Work, embrace truth

No gain in crawling about seeking help

None in procuring magic spells

Hustling everywhere without a clear goal

Or looking up to the sky for divine assitance.
 

5. AJOSEPO

Ìṣọ̀kan ni ó gbé wa d’ókè yí o

Ìgboyà ni ó gbé wa dé ‘bi iyì

Òtítọ́ ni ó mú wa d’òmìnira

Ìrẹ́pọ̀ ni ó gbé wa dé ‘bi ayọ̀

Kí l’ẹ wí?

A mí ṣe’un à jo ṣe pọ̀

A mí rìnrìn à jo rìn pọ̀

A mí jẹ’un à jo je pọ̀

A mí m’oun à jo mu pọ̀

Alábòsí bìlà, jẹ́ k’á r’ọ́nà
 

Ìfura, ṣe b’óun loògùn àgbà o

Ṣẹ̀ mí nbi ẹ́, ṣe b’óun ní m’ọ̀rẹ́ gùn

Òtítọ́ ni ó mú wa d’òmìnira

Ìrẹ́pọ̀ ni ó gbé wa dé ‘bi ògo

Kí l’ẹ wí?

A mí r’oun à jo rò pọ̀

A mí fa’un à jo fà pọ̀

A mí ru’un à jo rù pọ̀

A mí wo’bi à jo wọ̀ pọ̀

Oníbàjẹ́ yàgò, k’á rí ‘bi gbà

 

Alábòsí bìlà, jẹ́ k’á r’ọ́nà

Oníbàjẹ́ yàgò, k’á rí ‘bi gbà

Aláìmọ̀kan bìlà, jẹ́ k’á r’ọ́nà

Oníyangí yàgò, epo nmo rù
 

Unity is what will take us to the top

Courage will lift us to honour

Truth will lead us to freedom

Good relations will take us to the place of joy

And what do you say?

We are working together, as we should

We are walking together, as we should

We are feasting together, as we should

We are drinking together, as we should

 

Caution is the watchword of the elders

Openness is the key to a lasting friendship

Truth will lead us to freedom

Good relations will take us to the place of joy

And what do you say?

We are thinking together, as we should

We are pulling together, as we should

We are bearing the load together, as we should

We are entering the places together that we should

 

The dishonest, the destroyers and the clueless

Depart, stand aside

That our path may be clear.

 

6. STATUE IN LAGOS

There’s a statue in downtown Lagos 

Of a lady who sold her brothers and sisters

For mirrors and beads

She thought she had it made

But the Whiteman was done buying black flesh

The taste was changing in Europe, new beginnings

Now the battle lines are drawn

Ha hey oh, this land is not big enough for the two of us

Ha hey oh, pack your bags and leave here

Your time is up, your day is done

Go on, don’t look back.
 

There’s a little square in the town beneath a rock

Bears the name of the same crafty lady

Selling tools of war

She thought she had it made

But to the white man, she was a dealer in arms

A greedy criminal queen with hands in blood

Forever banished from this coast

Ha hey oh, this land is not big enough for the two of us

Ha hey oh, pack your bags and leave here

Your time is up, your day is done

Go on, don’t look back.

 

Hear the voices of the ones from the depth of the ocean

Listen to the voices of the ones who died on the slave ships

Can’t you hear the voices of the wretched ones you sold

Listen to the voices - 

Can you hear them, can you hear them?

 

7. EYE MEJILA

Ẹyẹ méjìlá l’órí igi, l’étí fèrèsé ilé mi

Wọ́n mí kọ’rin l’ òwúrọ̀ tí mo jí

Wọ́n mí kọ’rin ayọ̀

Wọ́n mí kọ’rin ìwúrí

Mo wá gbé’ra ní’lẹ̀ mo bọ́’júbọ́’nu

Mo gbé àpamọ́wọ́ mi, mo kó bàtà s’ẹ́sẹ̀

Ojú mà mí ro mí, àárẹ̀ m’ọ́kàn mi

Ẹyẹ ó dá’nu dúró o, wọ́n mí kọ’rin

Wọ́n mí kọ’rin ìgboyà

Wọ́n mí kọ’rin ìṣítí

Wọ́n ní: 

Ṣe gírí, múra jáde, òní mà ládùn púpọ̀

Ṣe kíákíá, yára bóóde, ire mà mí pè ọ́ o

 

Mo ṣí’lẹ̀kùn ilé, mo bọ́ s’óde

Mo rìn pàdé ẹbí pẹ̀l’álàdúgbò

Mo fi tẹ̀rìtẹ̀rìn kí gbogbo wọn

Mo mí kọ’rin ayọ̀

Mo mí kọ’rin ìwúrí

Mo mà d’óko òwò mi, mo wà ní’bi iṣẹ́

Mo pàdé ọ̀dọ́, mo mà r’ọ́mọdé níbẹ̀ o, pẹ̀l’ágbàlagbà

L’ọ́kùnrin l’óbìnrin

Mo r’ẹ́ni tí nronú, mo r’ẹ́ni tí nbẹ̀rù

Mo r’ẹ́ni tí ngbọ̀n l’ẹ́sẹ̀, t’ó nṣiyèméjì

Ma fi sùúrù kẹ́ wọn, ma tọ́ wọn s’ọ́nà

Mo mí kọ’rin ìgboyà

Mo mí kọ’rin ìṣítí

Mo ní:

Ṣe gírí, múra jáde, òní mà ládùn púpọ̀

Ṣe kíákíá, yára bóóde, ògo mà mí pè wá o
 

Twelve birds perched on a tree, just outside my window

Singing as I awoke in the morning

Singing songs of joy

Singing songs inspiration

So I got up, cleaned myself

Put on my shoes and picked up my bag

Still I had no desire, no drive

But the birds wouldn’t let up; they kept singing

Singing songs of encouragement

Singing songs of enlightenment

They said: come on now get going, 

Today is full of sweet promises

Come quickly, go out there,

Good fortune awaits you.

 

So I opened the door and stepped outside

There I meet my family and some neighbours

I greet them all heartily

Singing songs of joy

Singing songs inspiration

Settled at my place of work

I meet the youth, children, older people, male and female

Some deep in thought, some full of crippling fear

Some cowering, drowning in self-doubt

I comfort them and guide them gently

Singing songs of encouragement

Singing songs of enlightenment

I said: come on now get going,

Today is full of sweet promises

Come quickly, go out there,

True glory awaits us.
 

8. IGBE APA

B’ọ́mọ bá t’ọ́kọ́ ní ò, à fún l’ọ́kọ́

Ṣèbí ‘yẹn ọmọ t’ó mọ’kọ́ lò l’à nwí

Ọmọ t’á ò kọ́, ìyẹn á kó ti’lé tà pátá o

B’ó bá wá tà yẹn tán, á tún bọ́ s’óko

Á t’oko á ta’lẹ̀, á t’omi á t’odò

Á ta bàbá, ta yèyé, ta gbogbo ẹbí rẹ̀ pátá

Ẹ ò r’áyé wọn l’óde àwé (ọ̀rẹ́) ò, ni wọ́n nké

Ẹ w’ẹ̀sín wọn ní’ta o jàre

 

Agẹmọ ti bí’mọ rẹ̀, ó bí’mọ rẹ̀ sí’nú ẹwà

Àìmọ́ọ́jó ìyẹn wá d’ọwọ́ ọmọ ò

Ọmọ tí ò gb’ẹ̀kọ́, ìyẹn á k’àbámọ̀ ní’wájú o

L’ọ́jọ́ ìdààmú, á wá fa’jú roro

A w’òkè, á wo’lẹ̀, á w’òtún, á w’òsì

A wo bàbá, wo yèyé, pe gbogbo ẹbí rẹ̀ s’ẹ́kún

Ẹ ò r’áyé ’un l’óde àwé (ọ̀rẹ́) ò, l’ó nké

Ẹ w’ẹ̀sín ’un ní’ta o jàre
 

Àsàdànù l’ọmọde nsà ‘kuta ‘wájú ‘le bàbá rẹ̀

Bó bá pẹ́, ilé wọn á d’ahoro ò

Ọmọ t’á ò tọ́, ìyẹn á kó ti’lé tà pátá o

B’ó bá wá tà yẹ̀n tán, á tún bọ́ s’óko

Á t’oko á ta’lẹ̀, á t’omi, á t’odò

Á ta bàbá, ta yèyé, ta gbogbo ẹbí rẹ̀ pátá

Ẹ ò r’áyé wọn l’óde àwé (ọ̀rẹ́) ò, ni wọ́n nké

Ẹ w’ẹ̀sín wọn ní’ta o jàre

 

Ẹ jọ̀wọ́ ẹ t’ọ́mọ s’ọ́nà yeye (babá)

Ẹ jọ̀wọ́ ẹ k’ọ́mọ ní’wà rere
 

When a child is old enough to be given his own hoe we give it to him

That is a child who already knows how to use one

A child who has not been well trained will squander his family’s wealth

And he won’t stop until he has sold everything:

The land, the water, his parents and the whole family!

Watch them cry as they bemoan their sorry fate

Wailing, wallowing in shame and public disgrace.

 

The colourful masquerade has taught its progeny all the tricks

The onus is now on the young one to perform well

A child who rejects proper training will one day regret it

When trouble comes, he will be disheartened

Looking up and down, right and left, to his father, mother

Inviting the whole family to lamentation:

Oh, what has befallen us!

Oh, the shame, the public disgrace!

 

One by one the wasteful child throws away 

The building blocks of his father’s house

With time, the house will become a wreck

An untrained child will squander his family’s wealth

And he won’t stop until he has sold everything:

The land, the water, his parents and the whole family!

Watch them cry as they bemoan their sorry fate

Wailing, wallowing in shame public disgrace

 

Please show the children the proper way

Please teach the children good values

 

9. OLUMUYIWA

Jọ̀wọ́ bá mi gb’ẹ́ni mi d’ókè odò

Ó parí iṣẹ́ rẹ̀ ó ndàbọ̀ re ‘lé

Olumuyiwa ìyá Ẹgbẹ́ Oní-ìhìnrere

Abánitọ́mọ nre lé rẹ̀

Ọlọ́kọ̀, jọ̀wọ́ bá mi ṣ’ẹni mi ní jẹ́jẹ́

Ó j’èrè l’ọ́jà ó sì tún fì’wà lò’gbà

Olumuyiwa ìyá Ẹgbẹ́ Oní-ìhìnrere

Abánikẹ́mọ nre lé rẹ̀

 

Jọ̀wọ́ bá mi gb’ẹ́ni mi d’ókè odò

Ó bo’rí ìdánwò, ó yè kooro láyé

Olumuyiwa ìyá Ẹgbẹ́ Oní-ìhìnrere

Abánitọ́mọ nre lé rẹ̀

Ọlọ́kọ̀, jọ̀wọ́ bá mi ṣ’ẹni mi ní jẹ́jẹ́

Ó ṣe’wọ̀n t’ó lè ṣe, ó là’nà ayọ̀ ka’lẹ̀

Olumuyiwa ìyá Ẹgbẹ́ Oní-ìhìnrere

Abánikẹ́mọ nre lé rẹ̀

 

B’ó m’órin s’ẹ́nu, b’ó ṣe t’àdúrà

Gbogbo ilé á mì tìtìtìtì

B’ó bá ṣe ká fi’jó ṣè ‘dúpẹ́ 

Ẹ̀yin ẹ ṣá ma wò ó

 

Helmsman, please ferry my beloved to the shore

She’s done her duty and now returns home

Olumuyiwa, matron of the Good Tidings legion

Mother of Many goes back home.

Helmsman, please take good care of my beloved

She’s lived a good and profitable life

Olumuyiwa, matron of the Good Tidings legion

Mother of Many goes back home.
 

Helmsman, please ferry my beloved to the shore

She overcame her challenges in sparkling form

Olumuyiwa, matron of the Good Tidings legion

Mother of Many goes back home.

Helmsman, please take good care of my beloved

She did her best, built a path of joy

Olumuyiwa, matron of the Good Tidings legion

Mother of Many goes back home.
 

When she opens her mouth, in song or prayer

The house trembles to its foundations

And if it’s to dance merrily in gratitude

You just watch her go.

 

10. ONLANA

Mò nlọ l’óko mi ò mà l’ẹ́nìkankan

Mò nw’ọ̀nà f’ára mi

Mò nlà’nà f’ẹ́ni t’ó nbọ̀

Mò nṣè’wọ̀n tí mo lè ṣe

Bí mo bá nbọ̀ l’óde ma ṣè’bà f’ágbàgbà

Mi ò dè’nà m’ẹ́nìkankan

Mò nw’ọ̀nà f’ẹ́ni t’ó nbọ̀

Mò nṣè’wọ̀n tí mo lè ṣe

Kí’lé ayé wa dùn k’ó l’áyọ̀

K’a ṣè’wọ̀n t’a lè ṣe

K’a fì ‘yókù sí’lẹ̀

K’a là’nà f’ẹ́ni t’ó nbọ̀

K’a lè j’ogún ìdẹ̀ra pẹ̀l’áyọ̀ o

K’a j’èrè ìbàlẹ̀ ọkàn pẹ̀l’áyọ̀ o

 

Ẹgbẹ́ oníre l’àwa nbá rìn

Àwa ò gbìmọ̀ àdánìkanjẹ

À ngbèrò k’ó lè da o

A mí ṣè’tò kí aṣálẹ̀ k’ó dì ‘lú olóyin

Ẹ jẹ́ a gbé’ra ní’lẹ̀ k’á má ṣ’ọ̀lẹ

K’a ṣè’wọ̀n t’a lè ṣe

K’a fì ‘yókù sí’lẹ̀

K’a là’nà f’ẹ́ni t’ó nbọ̀

K’a lè j’ogún ìdẹ̀ra pẹ̀l’áyọ̀ o

K’a j’èrè ìbàlẹ̀ okàn pẹ̀l’áyọ̀ o

K’a lè j’ogún ìmolẹ̀ tí bo’rí òkùnkùn biri
 

I’m going my own way, not chasing after anyone

Looking out for myself, clearing the path for others

Doing the best I can.

Stepping out I pay homage to the elders

I’m not blocking anyone’s path

Looking out for those coming, doing the best I can.

That our time be full of joy and plenty

Let us do the best we can and leave the rest

Clear the path for future wayfarers

So that we may enjoy comfort, peace of mind and joy.

 

We are walking in the company of good people

Who don’t think in selfish and greedy ways

Always planning how to make things better for all

Working to turn a moribund society into a progressive one

Come on, let’s get going; do our best and leave the rest

Clear the path for future wayfarers

So that we may enjoy comfort, peace of mind and joy

And dazzling illumination that overcomes the deepest darkness.
 

11. VICTORY PARADE

Sweet lover, I have come to take you out to town

Where all the fun can be had

Oh, we’ll be dancing in the street (all through the night)

It’s the day we have all been waiting for

When the people will be free again

Oh, from the clutches of the vultures (and the bloodsuckers)

True love is our bond

Smiling faces all around

Arms reaching out in warm embrace

Oh, this is where we ought to be
 

Sweet lover, I am here to take away your pains

Move on up from this lonely place

Oh, leave the darkness behind (go into the light)

Out in town there’s a lively party going on

Everybody has hope again

Oh, it’s the dawn of a new day (a new beginning)

Trust is our banner

Honesty of purpose all the way

Arms linking up in unity

Oh, this is where we ought to be

 

Sweet lover, I have come again to say hello

My heart is pure and aglow

Oh, may this light never die (keep it burning bright)

Come dance with me

You’re the most beautiful of all

We have overcome backwardness and failure

You’re the best gain of all (you’re my victory)

Everyone is watching us

All clapping and cheering

It’s our turn on the dance floor

Oh, this is where we ought to be
 

Everyone is happy here

In this place of harmony

It’s our turn on the dance floor

Oh, this is where we ought to be
 

12. FOR ARIKE

Olólùfẹ́ àwa ọmọ Àríkẹ́

Ṣebí’wọ lo l’òní o, a dùn wò

Gbogbo ayé mà mí s’àfẹ́rí rẹ

Jíjó rẹ fún wa ká yọ̀ mọ́ ọ l’óde

Rọra máa gb’ẹ́sẹ̀ ní kànkan

 

Oníwàtútù yí ọmọ ìwúrí

Ṣèbí’wọ lo pè wá jọ, a mà dé o

Ojú rẹ dùn wò, ó ndá ni l’ọ́rùn

Sùgbọ́n ‘wà rẹ lo fi tàn bí òsùpá

Ilé rẹ wùn wá o ká jọ dé’bẹ̀

 

Ṣa ma ṣe tìrẹ o ọmọ àrídunnú

Má wo t’àwọn ẹlẹ́gàn agbẹ̀yìnṣebi

Òjòwú ayé ọ̀tá ìlọsíwájú

N’ọwọ́ rẹ s’ókè k’o dì mọ́’re òní

Olólùfẹ́ àwa Àríkẹ́ gẹ̀gẹ̀

 

Omọ́gbẹ̀kọ́ arẹwà adáraníjó

Bó bá s’ọgbọ́n, o ní yẹn, oò rẹ̀wẹ̀sì

Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ mà gbé ọ lékè

Inú àwa mà ndùn láti mọ̀ ọ́

Ìjòkó ẹ̀yẹ rẹ wà l’óde máa bọ̀

 

Gbé’ra n’ílẹ̀, òní l’ọjọ́ iyì rẹ

A dé, a bá ẹ yọ̀

 

Sweet darling Arike

Today’s your special day our beautiful one

The whole world awaits your grand entrance

Do that dance as we celebrate with you

Go gently one step at a time

 

Sweet-tempered one, our source of pride

You invited us all and here we are

It’s such a joy to behold your alluring face

But your good character is what really glows like the moon

We’d be honored to follow you home


Just keep doing your thing, our fountain of happiness

Ignore the detractors who hide to do their evil

They are just envious people, enemies of progress

Reach out and embrace today’s blessings

Our sweet, sweet darling Arike

 

Well-trained and beautiful one; splendid dancer

When it comes to wisdom, you’ve got that too

Your good works have lifted you high

We are so proud to know you

Come on out and take your seat of glory
 

Come on now, today’s your day of honour

We have all come to celebrate with you.
 

13. NO WORDS

We don’t need no music in the air

We dance to silence

We don’t have to work so hard for it

Come on close, hold on tight.

Your eyes, bright as day

Deep in your gorgeous eyes, mysteries lurking

We don’t need no words

We’ve got it.

Your eyes, bright and gay

Oh your beautiful eyes, it’s truly magic

We don’t need no words

We’ve got it.

 

We’re the rhythm of the wet and dry

Take it easy, take it slow

We’re the reason the rain fell last night

Cuddle close, nestle here.

Your eyes, dark as night

There in your shiny eyes, thrills and twinkles

We don’t need no words

We’re steady.

Your eyes, sweet delight

Oh your beautiful eyes, pomp and laughter

We don’t need no words

We’ve got it.

 

14. ENISUNGBALAJA

Orí nṣaájò f’órí k’órí k’ó lè ba sunwọ̀n

Ọwọ́ nṣaájò f’ọ́wọ́ k’á r’óun tó dùn ṣe l’óde

Ló d’ífá fún ẹni sùn gbalaja tó gb’ojú àlá w’ọjà

Èèló l’ẹ̀ ntà’dùnnú, èèló nì’bàlẹ̀ ọkàn

Èèló l’ẹ̀ ntà’lọsíwájú, èèló l’ayọ̀?

 

Ibi orí dá ni sí làágbé, kì ṣe ti ká jòkó tẹ̀tẹ̀rẹ̀

Ojú ayé a tàn roboto

Ọ̀nà là f’ẹ̀ni tí nṣè’bà èrò ọ̀nà

Ló d’ífá fún ẹni sùn gbalaja tó gb’ojú àlá w’ọjà

Èèló l’ẹ̀ ntà’dùnnú, èèló nì’bàlẹ̀ ọkàn

Èèló l’ẹ̀ ntà’lọsíwájú, èèló l’ayọ̀?

 

Where is the sunshine beyond the dark night?

When is the rain beyond the drought?

What lies beyond the bend for the roaring river?

Ọ̀yẹ̀ là ọ̀yẹ̀ là, ojú là kedere o

Ọ̀yẹ̀ là ọ̀yẹ̀ là, ọjọ́ là kedere o

Ọ̀yẹ̀ là ọ̀yẹ̀ là, ọ̀na là kedere o

 

Ọjọ́ òní a p’ẹ̀dá s’éré

Ọjọ́ àná l’àgbà ìwà

Ọjọ́ ọ̀la nbọ̀ wá kánkán

Adùn f’ẹ̀ni tó m’òye àsìkò

Ló d’ífá fún ẹni sùn gbalaja tó gb’ojú àlá w’ọjà

Èèló l’ẹ̀ ntà’dùnnú, èèló nì’bàlẹ̀ ọkàn

Èèló l’ẹ̀ ntà’lọsíwájú, èèló l’ayọ̀?
 

Head pleads for Head, that one should prosper

Hand pleads for Hand, that our efforts may meet with success

So said the Ifa oracle to He-Who-Soundly-Slept

Who entered a market in his dream

“How much do you sell Happiness?

How much for Peace of Mind?

How much do you sell Progress?

How much for Joy?”

 

You prosper where destiny has planted you

That’s not an excuse to sit and do nothing

The world is wide open and large

The path opens for those who acknowledge other wayfarers

So said the Ifa oracle to He-Who-Soundly-Slept

Who entered a market in his dream

“How much do you sell Happiness?

How much for Peace of Mind?

How much do you sell Progress?

How much for Joy?”

 

Open wide and clear, may all eyes be opened

Open wide and clear, may the day break brightly

Open wide and clear, may the path open wide

 

Today calls us to a race

Yesterday is the past of being

Tomorrow arrives quickly

Delight for those who understand times and seasons

So said the Ifa oracle to He-Who-Soundly-Slept

Who entered a market in his dream

“How much do you sell Happiness?

How much for Peace of Mind?

How much do you sell Progress?

How much for Joy?”

 

15. CLUB 54

The other day I was sitting there just minding my business

When she says to me, “Well, it’s time to go”

Feet are lead, heart is gold, 

I really think you should go on alone and let me be

Or just hold my glass

Cos the way I feel now I’d just like to dance all night

 

I’ve lived the stories, borne the loss, been there and done that

And it’s just all lies, doesn’t move me anymore

You can play your politics, make your money

Just leave me out of your silly games

I’ve got some way to go and time is not my friend

Cos the way I feel now I’d just like to dance all night

 

Tell me, dear, are the lights not flashing?

I think it’s my turn on the dance floor

Come on love, catch me if you can

The way I feel now I’d just like to dance all night

 

I’m done with pain, done with sorrow

In this place no one can touch me

Shut the door on your rotten heroes

Cos the way I feel now I’d just like to dance all night.

8 comments